Yorùbá

IBA Montage

A pe ajo rẹ lati fi awọn titẹ sii silẹ fun 2025 International Business Awards® (ọdun 22), eto awọn ẹbun iṣowo ti o ga julọ ni agbaye.

Tẹ́ ẹ bá fẹ́ gba ìsọfúnni tó kún rẹ́rẹ́ nípa bẹ́ ẹ ṣe lè múra sílẹ̀, kẹ́ ẹ sì kópa, ẹ fi àdírẹ́sì orí ìkànnì yín ránṣẹ́ sí wa. Àá sì fi ṣọwọ́ sí i yín. A mọ̀ pé òfin tó de ìsọfúnni ara ẹni, torí náà, ẹ fọkàn balẹ̀, a ò ní pín àdírẹ́sì yín kiri fún ẹnikẹ́ni.

 

 

Abala kan ṣoṣo tẹ́ ẹ ti máa rí èdè yìí rèé lórí ìkànnì wa Gẹ̀ẹ́sì la fi kọ gbogbo abala tó kù Ìdí ni pé èdè Gẹ̀ẹ́sì la retí pé kẹ́ ẹ fi kọ gbogbo ìsọfúnni nípa àwọn tẹ́ ẹ yàn ránṣẹ́ sí wa, ìyẹn á mú kó rọrùn fún àwọn ṣòwòṣòwò wa kárí ayé láti kópa nínú yíyan ẹni tó to yẹ.

 

Nípa Àmì Ẹ̀yẹ Ìṣòwò Kárí Ayé (IBA)

Ètò Àmì Ẹ̀yẹ Ìṣòwò Kárí Ayé (IBA) ni ètò kan ṣoṣo táwọn èèyàn mọ̀ kárí ayé tó ń fúnni ní àmì ẹ̀yẹ ní gbogbo ẹ̀ka iléeṣẹ́ fún iṣẹ́ akin tí wọ́n ṣe. Àjọ Àmì Ẹ̀yẹ Stevie, tó ń ṣojú láti fúnni ní àmì èyẹ̀ náà wà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Àwa la ṣètò ìdíje méje fún Àmì Ẹ̀yẹ Stevie tó kọ́já. O lè mọ̀ púpọ̀ sí í nípa rẹ̀ lórí ìkànnì www.StevieAwards.com. Ife Àmì Ẹ̀yẹ Stevie ti di ohun tí ohun tí gbogbo èèyàn ń lé.

Ni ọdun 2024, a fun International Stevie Awards si awọn ẹgbẹ ati awọn eniyan kọọkan lati awọn orilẹ-ede to ju 60 lọ. Tẹ ibi lati wo àtòkọ awọn to jáwé olúborí ninu abala 2024.

 

Ìsọ̀rí

Ìsọ̀rí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Àmì Ẹ̀yẹ Ìṣòwò Kárí Ayé (IBA) pín sí. Tó o bá fẹ́ kópa, wàá mú ìsọ̀rí tó bá mọ̀ pé ó bá ẹ mu tàbí tí iléeṣẹ́ ẹ fẹ́ kí wọ́n fún àwọn ní àmì ẹ̀yẹ fún. Lẹ́yìn náà, tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà níbẹ̀ kó o sì yan àwọn tó o fẹ́ Díẹ̀ lára àwọn ìsọ̀rí tó wà ní:

• Àmì Ẹ̀yẹ fún Iléeṣẹ́ tó ta yọ jù lọ
• Àmì Ẹ̀yẹ fún Aṣojú Iléeṣẹ́ tó ta yọ jù lọ
• Àmì Ẹ̀yẹ fún Oníbàárà tó ta yọ jù lọ
• Àmì Ẹ̀yẹ fún Agbanisíṣẹ́ tó ta yọ jù lọ
• Àmì Ẹ̀yẹ fún Ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ Kọ̀ǹpútà
• Àmì Ẹ̀yẹ fún Ètò Iléeṣẹ́
• Àmì Ẹ̀yẹ fún Ìpolówó Ọjà
• Àmì Ẹ̀yẹ fún oríṣiríṣi ohun tó nííṣe pẹ̀lú ìkànnì, Ìròyìn Ọdọọdún, Ètò, àti fídíò
• Àmì Ẹ̀yẹ fún Ìtẹ̀síwájú Ìṣòwò
• Àmì Ẹ̀yẹ fún Ohun Tuntun Tó Jáde

Àlàyé lórí ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan, ohun tẹ́ ẹ máa fi ránṣẹ́ lórí ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan, ìgbà tó yẹ kẹ́ ẹ fi ránṣẹ́ àti iye owó tí ọ̀kọ̀ọ̀kan máa ná yín wà ninú ìsọfúnni tá a fi ránṣẹ́.

Nínú àwọn ìsọ̀rí tí ó pọ̀ jùlọ o lè yàn láti ṣe ìfikalẹ̀ fidio tí ó tó ìṣẹ́jú márún nípa àwọn àṣeyọrí rẹ tàbí ti àjọ rẹ ní àwọn ìsọ̀rí tí o yàn, tàbí àwọn ìdáhùn àfọwọ́kọ sí àwọn ìbéèrè àwọn ìsọ̀rí náà.

 

Àmì ẹ̀yẹ

Awọn olubori ti International Stevie Awards fun ọdun 2025 ni yoo kede ni ọjọ 13th ti Oṣu Kẹjọ. Lẹ́yìn náà, a ó ṣe ìfifúnni àwọn ife ẹ̀yẹ pẹ̀lú Àmì Bàbà àti Idẹ Stevie Award níbi ayẹyẹ kan ní Europe ní oṣù kẹwàá ọdún.

 

Àdírẹ́sì

Jọ̀wọ́ kàn sí wa tó o bá ní ìbéèrè nípa Àmì Ẹ̀yẹ Ìṣòwò Kárí Ayé (IBA) tàbí Àmì Ẹ̀yẹ Stevie tàbí ètò míràn.

The Stevie Awards
10560 Main Street, Suite 519
Fairfax, Virginia 22030, USA
Fóònù: +1 703-547-8389
Fax: +1 703-991-2397
Àdírẹ́sì email: help@stevieawards.com